Isaiah 54:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Isaiah 54:5 in English
Isaiah 54:5 · Berean Standard Bible
For your husband is your Maker— the LORD of Hosts is His name— the Holy One of Israel is your Redeemer; He is called the God of all the earth.
Context
3Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn. 4“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ,
ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́. 5Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé. 6Olúwa yóò pè ọ́ padà
àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí. 7“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
mú ọ padà wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.