Isaiah 54:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì; ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
Isaiah 54:3 in English
Isaiah 54:3 · Berean Standard Bible
For you will spread out to the right and left; your descendants will dispossess the nations and inhabit the desolate cities.
Context
1“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
ni Olúwa wí. 2Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
sọ okùn rẹ di gígùn,
mú òpó rẹ lágbára sí i. 3Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn. 4“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ,
ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́. 5Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.