Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

Isaiah 54:8 in English

Isaiah 54:8 · Berean Standard Bible

In a surge of anger I hid My face from you for a moment, but with everlasting kindness I will have compassion on you,” says the LORD your Redeemer.

Context

6Olúwa yóò pè ọ́ padà àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ tí a sì bà lọ́kàn jẹ́ obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́, tí a sì wá jákulẹ̀,” ni Olúwa wí. 7“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò mú ọ padà wá. 8Ní ríru ìbínú. Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun Èmi yóò síjú àánú wò ọ́,” ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí. 9“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́. 10Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí, síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.