Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

Isaiah 52:6 in English

Isaiah 52:6 · Berean Standard Bible

Therefore My people will know My name; therefore they will know on that day that I am He who speaks. Here I am!”

Context

4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí. “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti gbé; láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú. 5“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni Olúwa wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo. 6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.” 7Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!” 8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.