Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

Isaiah 52:7 in English

Isaiah 52:7 · Berean Standard Bible

How beautiful on the mountains are the feet of those who bring good news,* who proclaim peace, who bring good tidings, who proclaim salvation, who say to Zion, “Your God reigns!”

Context

5“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni Olúwa wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo. 6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.” 7Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!” 8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn. 9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.