Isaiah 52:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọn eruku rẹ kúrò; dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu. Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.
Isaiah 52:2 in English
Isaiah 52:2 · Berean Standard Bible
Shake off your dust! Rise up and sit on your throne, O Jerusalem. Remove the chains from your neck, O captive Daughter of Zion.
Context
1Jí, jí, ìwọ Sioni,
wọ ara rẹ ní agbára.
Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
kì yóò wọ inú rẹ mọ́. 2Gbọn eruku rẹ kúrò;
dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu.
Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni. 3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,
“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.” 4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.
“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
lọ sí Ejibiti láti gbé;
láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.