Isaiah 51:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
Isaiah 51:19 in English
Isaiah 51:19 · Berean Standard Bible
These pairs have befallen you: devastation and destruction, famine and sword. Who will grieve for you? Who can comfort you?*
Context
17Jí, jí!
Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu,
ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa
ago ìbínú rẹ̀,
ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀
tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n. 18Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí
kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà
nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́
kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́. 19Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—
ta ni yóò tù ọ́ nínú?
Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà
ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn? 20Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;
wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,
gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.
Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́
àti ìbáwí Ọlọ́run yín. 21Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,
tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.