Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Isaiah 51:15 in English

Isaiah 51:15 · Berean Standard Bible

For I am the LORD your God who stirs up the sea so that its waves roar— the LORD of Hosts is His name.

Context

13tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà? 14Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà. 15Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 16Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ” 17Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.