Isaiah 51:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
Isaiah 51:14 in English
Isaiah 51:14 · Berean Standard Bible
The captive will soon be freed; he will not die in the dungeon, and his bread will not be lacking.
Context
12“Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.
Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,
àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán, 13tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,
ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run
tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́
nítorí ìbínú àwọn aninilára,
tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun?
Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà? 14Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ
wọn kò ní kú sínú túbú wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà. 15Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí
ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 16Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ
mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́,
Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,
àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé,
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.