Isaiah 49:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
Isaiah 49:25 in English
Isaiah 49:25 · Berean Standard Bible
Indeed, this is what the LORD says: “Even the captives of the mighty will be taken away, and the plunder of the tyrant will be retrieved; I will contend with those who contend with you, and I will save your children.
Context
23Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,
àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.
Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;
wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa;
gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi
ni a kì yóò jákulẹ̀.” 24Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,
tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú? 25Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,
àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;
ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,
àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà. 26Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn;
wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì.
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀
pé, Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ,
Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.