Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?

Isaiah 49:24 in English

Isaiah 49:24 · Berean Standard Bible

Can the plunder be snatched from the mighty, or the captives of a tyrant * be delivered?

Context

22Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí, “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà, Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn. 23Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́. Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀; wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀.” 24Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú? 25Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà. 26Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran-ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.