Isaiah 49:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
Isaiah 49:20 in English
Isaiah 49:20 · Berean Standard Bible
Yet the children of your bereavement will say in your hearing, ‘This place is too small for us; make room for us to live here.’
Context
18Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó. 19“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro
tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,
ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò
wà láti ọ̀nà jíjìn réré. 20Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ
yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,
‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;
ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’ 21Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,
‘Ta ló bí àwọn yìí fún mi?
Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;
a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.
Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?
A fi èmi nìkan sílẹ̀,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ” 22Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí,
“Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà,
Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;
wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn
wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin
ní èjìká wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.