Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun, ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò wà láti ọ̀nà jíjìn réré.

Isaiah 49:19 in English

Isaiah 49:19 · Berean Standard Bible

For your ruined and desolate places and your ravaged land will now indeed be too small for your people, and those who devoured you will be far away.

Context

17Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ. 18Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká; gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́; ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó. 19“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun, ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò wà láti ọ̀nà jíjìn réré. 20Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’ 21Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ló bí àwọn yìí fún mi? Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn; a sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀. Ta ló wo àwọn yìí dàgbà? A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.