Isaiah 49:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
Isaiah 49:16 in English
Isaiah 49:16 · Berean Standard Bible
Behold, I have inscribed you on the palms of My hands; your walls are ever before Me.
Context
14Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa ti gbàgbé è mi.” 15“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé,
Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! 16Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo. 17Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,
àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ. 18Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.