Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!

Isaiah 49:15 in English

Isaiah 49:15 · Berean Standard Bible

“Can a woman forget her nursing child, or lack compassion for the son of her womb? Even if she could forget, I will not forget you!

Context

13Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú. 14Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.” 15“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! 16Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo. 17Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.