Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

Isaiah 47:3 in English

Isaiah 47:3 · Berean Standard Bible

Your nakedness will be uncovered and your shame will be exposed. I will take vengeance; I will spare no one.”

Context

1“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúńdíá ọmọbìnrin Babeli; jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́. 2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú rẹ kúrò. Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan, kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá. 3Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀san, Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.” 4Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli. 5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Babeli; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.