Isaiah 46:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
Isaiah 46:9 in English
Isaiah 46:9 · Berean Standard Bible
Remember what happened long ago, for I am God, and there is no other; I am God, and there is none like Me.
Context
7Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,
wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.
Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà.
Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;
òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀. 8“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,
fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀. 9Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi. 10Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
Mo wí pé, Ète mi yóò dúró,
àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí. 11Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.