Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.

Isaiah 46:7 in English

Isaiah 46:7 · Berean Standard Bible

They lift it to their shoulder and carry it along; they set it in its place, and there it stands, not budging from that spot. They cry out to it, but it does not answer; it saves no one from his troubles.

Context

5“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara? 6Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín. 7Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà. Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀. 8“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀. 9Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.