Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.

Isaiah 46:3 in English

Isaiah 46:3 · Berean Standard Bible

“Listen to Me, O house of Jacob, all the remnant of the house of Israel, who have been sustained from the womb, carried along since birth.

Context

1Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú. 2Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀; wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn. 3“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu, gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli, ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ. 4Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀. 5“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.