Isaiah 46:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
Isaiah 46:1 in English
Isaiah 46:1 · Berean Standard Bible
Bel crouches; Nebo cowers. Their idols weigh down beasts and cattle. The images you carry are burdensome, a load to the weary animal.
Context
1Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;
àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.
Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di
àjàgà sí wọn lọ́rùn,
ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú. 2Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
wọn kò lè gba ẹrù náà,
àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn. 3“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.