Isaiah 46:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín, Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
Isaiah 46:4 in English
Isaiah 46:4 · Berean Standard Bible
Even to your old age, I will be the same, and I will bear you up when you turn gray. I have made you, and I will carry you; I will sustain you and deliver you.
Context
2Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
wọn kò lè gba ẹrù náà,
àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn. 3“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ. 4Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín,
Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.
Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;
Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀. 5“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?
Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi
tí àwa yóò jọ fi ara wé ara? 6Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn
wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n;
wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,
wọn sì tẹríba láti sìn ín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.