Isaiah 45:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
Isaiah 45:22 in English
Isaiah 45:22 · Berean Standard Bible
Turn to Me and be saved, all the ends of the earth; for I am God, and there is no other.
Context
20“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;
ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá.
Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,
tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni. 21Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá,
jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.
Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,
ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?
Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?
Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,
Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;
kò sí ẹlòmíràn àfi èmi. 22“Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,
ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;
nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn. 23Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,
ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,
ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.
Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;
nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra. 24Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni
òdodo àti agbára wà.’ ”
Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;
yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.