Isaiah 44:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
Isaiah 44:27 in English
Isaiah 44:27 · Berean Standard Bible
who says to the depths of the sea, ‘Be dry, and I will dry up your currents,’
Context
25ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́
tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀, 26ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,
“ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’
àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’
àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’ 27ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,
èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’ 28ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi
àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;
òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”
àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.