Isaiah 44:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
Isaiah 44:25 in English
Isaiah 44:25 · Berean Standard Bible
who foils the signs of false prophets and makes fools of diviners, who confounds the wise and turns their knowledge into nonsense,
Context
23Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;
kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà,
ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli. 24“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́
láti inú ìyá rẹ wá:
“Èmi ni Olúwa
tí ó ti ṣe ohun gbogbo
tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run
tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀, 25ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́
tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀, 26ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,
“ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’
àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’
àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’ 27ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,
èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.