Isaiah 44:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà; òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé, “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
Isaiah 44:20 in English
Isaiah 44:20 · Berean Standard Bible
He feeds on ashes. His deluded heart has led him astray, and he cannot deliver himself or say, “Is not this thing in my right hand a lie?”
Context
18Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan. 19Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
láti sọ wí pé,
“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?” 20Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé,
“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?” 21“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu,
nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.
Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,
ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ. 22Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.
Padà sọ́dọ̀ mi,
nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.