Isaiah 44:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
Isaiah 44:18 in English
Isaiah 44:18 · Berean Standard Bible
They do not comprehend or discern, for He has shut their eyes so they cannot see and closed their minds so they cannot understand.
Context
16Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.” 17Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.” 18Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan. 19Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
láti sọ wí pé,
“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?” 20Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé,
“Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.