Isaiah 44:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
Isaiah 44:16 in English
Isaiah 44:16 · Berean Standard Bible
He burns half of it in the fire, and he roasts meat on that half. He eats the roast and is satisfied. Indeed, he warms himself and says, “Ah! I am warm; I see the fire.”
Context
14Ó gé igi kedari lulẹ̀,
tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà. 15Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;
díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí
ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,
ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.
Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;
ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un. 16Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.” 17Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.” 18Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.