Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”

Isaiah 42:9 in English

Isaiah 42:9 · Berean Standard Bible

Behold, the former things have happened, and now I declare new things. Before they spring forth I proclaim them to you.”

Context

7láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn. 8“Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà. 9Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.” 10Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn. 11Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.