Isaiah 42:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
Isaiah 42:7 in English
Isaiah 42:7 · Berean Standard Bible
to open the eyes of the blind, to bring prisoners out of the dungeon and those sitting in darkness out from the prison house.
Context
5Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí
Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀: 6“Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo,
Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà 7láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn. 8“Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn
tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà. 9Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,
àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;
kí wọn tó hù jáde
mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.