Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.

Isaiah 42:10 in English

Isaiah 42:10 · Berean Standard Bible

Sing to the LORD a new song— His praise from the ends of the earth— you who go down to the sea, and all that is in it, you islands,* and all who dwell in them.

Context

8“Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà. 9Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.” 10Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn. 11Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè. 12Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.