Isaiah 42:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.
Isaiah 42:12 in English
Isaiah 42:12 · Berean Standard Bible
Let them give glory to the LORD and declare His praise in the islands.
Context
10Kọ orin tuntun sí Olúwa
ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,
ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀,
ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn. 11Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè;
jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀.
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀;
jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè. 12Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa
àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù. 13Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,
yóò ru owú sókè bí ológun;
yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun,
òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. 14“Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,
mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró.
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí,
mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.