Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Isaiah 42:13 in English

Isaiah 42:13 · Berean Standard Bible

The LORD goes forth like a mighty one; He stirs up His zeal like a warrior. He shouts; yes, He roars in triumph over His enemies:

Context

11Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè. 12Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù. 13Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. 14“Fún ìgbà pípẹ́ ni mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo ti wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kó ara ró. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí, mo sọkún, mo sì ń mí hẹlẹ hẹlẹ. 15Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.