Isaiah 41:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
èkínní ran èkejì lọ́wọ́ ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!”
Isaiah 41:6 in English
Isaiah 41:6 · Berean Standard Bible
Each one helps the other and says to his brother, “Be strong!”
Context
4Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,
tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?
Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn
àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.” 5Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;
ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.
Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú; 6èkínní ran èkejì lọ́wọ́
ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!” 7Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,
àti ẹni tí ó fi òòlù dán
mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.
Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”
Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀. 8“Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi,
Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn,
ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.