Isaiah 41:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
Isaiah 41:4 in English
Isaiah 41:4 · Berean Standard Bible
Who has performed this and carried it out, calling forth the generations from the beginning? I, the LORD—the first and the last— I am He.”
Context
2“Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá,
tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?
Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́
ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀.
Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,
láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀. 3Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà,
ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí. 4Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,
tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?
Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn
àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.” 5Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;
ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.
Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú; 6èkínní ran èkejì lọ́wọ́
ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.