Isaiah 41:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan— kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá, kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.
Isaiah 41:28 in English
Isaiah 41:28 · Berean Standard Bible
When I look, there is no one; there is no counselor among them; when I ask them, they have nothing to say.
Context
26Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀,
tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’?
Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,
ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,
ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 27Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Wò ó, àwọn nìyìí!’
Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan. 28Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—
kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,
kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n. 29Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn!
Gbogbo ìṣe wọn jásí asán;
àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.