Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.

Isaiah 40:3 in English

Isaiah 40:3 · Berean Standard Bible

A voice of one calling: “Prepare the way for the LORD in the wilderness;* make a straight highway for our God in the desert.*

Context

1Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí. 2Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 3Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. 4Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ. 5Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀, gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.