Isaiah 40:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Isaiah 40:2 in English
Isaiah 40:2 · Berean Standard Bible
“Speak tenderly to Jerusalem, and proclaim to her that her forced labor has been completed; her iniquity has been pardoned. For she has received from the hand of the LORD double for all her sins.”
Context
1Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,
ni Ọlọ́run yín wí. 2Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu
kí o sì kéde fún un
pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,
pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa
ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 3Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:
“Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. 4Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè,
gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti
ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.