Isaiah 38:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”
Isaiah 38:10 in English
Isaiah 38:10 · Berean Standard Bible
I said, “In the prime * of my life I must go through the gates of Sheol and be deprived of the remainder of my years.”
Context
8Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀. 9Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán. 10Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi
èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú
kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?” 11Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,
àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,
tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń
gbe orílẹ̀ ayé báyìí. 12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;
ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.