Isaiah 38:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́, àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè; èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń gbe orílẹ̀ ayé báyìí.
Isaiah 38:11 in English
Isaiah 38:11 · Berean Standard Bible
I said, “I will never again see the LORD, even the LORD, in the land of the living; I will no longer look on mankind with those who dwell in this world.
Context
9Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán. 10Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi
èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú
kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?” 11Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,
àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,
tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń
gbe orílẹ̀ ayé báyìí. 12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;
ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi. 13Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,
ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;
ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.