Isaiah 37:30
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
Isaiah 37:30 in English
Isaiah 37:30 · Berean Standard Bible
And this will be a sign to you, O Hezekiah: This year you will eat what grows on its own, and in the second year what springs from the same. But in the third year you will sow and reap; you will plant vineyards and eat their fruit.
Context
28“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà
àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ
àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi. 29Nítorí pé inú rẹ ru sí mi
àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti
dé etí ìgbọ́ mi,
Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,
àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,
èmi yóò sì jẹ́ kí o padà
láti ọ̀nà tí o gbà wá. 30“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,
ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn. 31Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda
yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè. 32Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,
àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.