Isaiah 37:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
Isaiah 37:28 in English
Isaiah 37:28 · Berean Standard Bible
But I know your sitting down, your going out and coming in, and your raging against Me.
Context
26“Ṣé o kò tí ì gbọ́?
Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.
Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;
ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,
pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di
àkójọpọ̀ àwọn òkúta. 27Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,
ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.
Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,
gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,
tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè. 28“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà
àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ
àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi. 29Nítorí pé inú rẹ ru sí mi
àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti
dé etí ìgbọ́ mi,
Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,
àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,
èmi yóò sì jẹ́ kí o padà
láti ọ̀nà tí o gbà wá. 30“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah:
“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,
ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.