Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.

Isaiah 37:31 in English

Isaiah 37:31 · Berean Standard Bible

And the surviving remnant of the house of Judah will again take root below and bear fruit above.

Context

29Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá. 30“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn. 31Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè. 32Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ. 33“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.