Isaiah 36:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀,
Isaiah 36:16 in English
Isaiah 36:16 · Berean Standard Bible
Do not listen to Hezekiah, for this is what the king of Assyria says: Make peace with me * and come out to me. Then every one of you will eat from his own vine and his own fig tree, and drink water from his own cistern,
Context
14Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’ 16“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà. 18“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.