Isaiah 36:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀!
Isaiah 36:14 in English
Isaiah 36:14 · Berean Standard Bible
This is what the king says: Do not let Hezekiah deceive you, for he cannot deliver you.
Context
12Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?” 13Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 14Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’ 16“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.