Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria!

Isaiah 36:13 in English

Isaiah 36:13 · Berean Standard Bible

Then the Rabshakeh stood and called out loudly in Hebrew: “Hear the words of the great king, the king of Assyria!

Context

11Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.” 12Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?” 13Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 14Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.