Isaiah 36:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
Isaiah 36:17 in English
Isaiah 36:17 · Berean Standard Bible
until I come and take you away to a land like your own—a land of grain and new wine, a land of bread and vineyards.
Context
15Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’ 16“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà. 18“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí? 19Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Samaria gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.