Isaiah 36:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí?
Isaiah 36:18 in English
Isaiah 36:18 · Berean Standard Bible
Do not let Hezekiah mislead you when he says, ‘The LORD will deliver us.’ Has the god of any nation ever delivered his land from the hand of the king of Assyria?
Context
16“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà. 18“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí? 19Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Samaria gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí? 20Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.