Isaiah 33:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀ yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
Isaiah 33:17 in English
Isaiah 33:17 · Berean Standard Bible
Your eyes will see the King in His beauty and behold a land that stretches afar.
Context
15Ẹni tí ó ń rìn lódodo
tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi, 16Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,
ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.
A ó mú oúnjẹ fún un,
omi rẹ̀ yóò sì dájú. 17Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀
yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ. 18Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:
“Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?
Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?
Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?” 19Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,
àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,
pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.