Isaiah 32:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.
Isaiah 32:5 in English
Isaiah 32:5 · Berean Standard Bible
No longer will a fool be called noble, nor a scoundrel be respected.
Context
3Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀. 4Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege. 5A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́
tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn. 6Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:
òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run
ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;
ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo
àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ
ni ó mú omi kúrò. 7Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
ó ń gba èrò búburú
láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.