Isaiah 32:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà, fún àwọn àjàrà eléso
Isaiah 32:12 in English
Isaiah 32:12 · Berean Standard Bible
Beat your breasts for the pleasant fields, for the fruitful vines,
Context
10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí. 11Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn;
bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín. 12Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
fún àwọn àjàrà eléso 13àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi,
ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n,
bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
àti fún ìlú àríyá yìí. 14Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.